Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  July 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Lè Gbìyànjú Rẹ̀ Wò fún Ọdún Kan?

Ṣé O Lè Gbìyànjú Rẹ̀ Wò fún Ọdún Kan?

Gbìyànjú kí ni? Aṣáájú-ọ̀nà déédéé! Tó o bá gbìyànjú ẹ̀ wò, wàá rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún!—Owe 10:22.

TÓ O BÁ Ń ṢIṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ . . .

  • wàá sunwọ̀n sí i gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, wàá sì túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù

  • wàá túbọ̀ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Bó o bá ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fún àwọn èèyàn ni wàá ṣe túbọ̀ máa rántí àwọn àgbàyanu ànímọ́ rẹ̀

  • wàá ní ìfọ̀kànbalẹ̀ téèyàn máa ń ní tó bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ àti ayọ̀ tó máa ń wá láti inú ríran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.—Mt 6:33; Iṣe 20:35

  • wàá lè lọ sí ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa ń bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe, àkànṣe ìpàdé nígbà àpéjọ àyíká àti Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà

  • wàá láǹfààní púpọ̀ sí i láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá sì máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀

  • wàá máa lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará, wàá sì gbádùn pàṣípààrọ̀ ìṣírí.—Ro 1:11, 12