Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń wàásù fún obìnrin kan tó ń já ewé lóko lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI July 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! lọni. Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ Yin Jèhófà, Olùgbọ́ Àdúrà

Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa gbàdúrà nípa àwọn ìlérí tó o ṣe fún Ọlọ́run? Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú àdúrà rẹ? (Sáàmù 61-65)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kí Ohun Díẹ̀ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn Kó O Lè Túbọ̀ Máa Yin Ọlọ́run

Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn? Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwọn Èèyàn Jèhófà Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́

Kí la rí kọ́ nínú bí Dáfídì ṣe jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́? Kí ni ìtara tá a ní fún ìjọsìn tòótọ́ ń mú ká ṣe? (Sáàmù 69-72)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Lè Gbìyànjú Rẹ̀ Wò fún Ọdún Kan?

Àwọn tó bá gbìyànjú ẹ̀ wò máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún, ọkàn wọn á sì balẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé

Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí i pé àwọn tí wọ́n ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè tàbí tí wọ́n ní àìlera lè ṣe iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Máa Rántí Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà

Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ Jèhófà? Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣàṣàrò lórí wọn? (Sáàmù 74-78)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?

Ẹni tó kọ Sáàmù 83 fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run ni ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Báwo ni àwa náà ṣe lè fi hàn bẹ́ẹ̀?