Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  January 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 38-42

Jèhófà Ń Fi Agbára fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀

Jèhófà Ń Fi Agbára fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀

40:​29-31

  • Ẹyẹ idì lè wà lójú òfuurufú fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Afẹ́fẹ́ olóoru tó wà lójú sánmà ló máa ń lò. Tí ẹyẹ idì bá ti dé ibi tí afẹ́fẹ́ tó móoru wà, á máa fò yípo, afẹ́fẹ́ náà á sì máa gbé e lọ sókè. Tó bá ti wá fò dókè dáadáa, á tún bọ́ sínú afẹ́fẹ́ míì tó móoru ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, á sì tún máa fò yípo

  • Bó ṣe dà bíi pé ẹyẹ idì kì í lo agbára tó bá ń fò jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń fún wa ní agbára tó ń jẹ́ ká lè máa bá ìjọsìn wa lọ