Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  January 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 24-28

Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Àwọn Èèyàn Rẹ̀

Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Àwọn Èèyàn Rẹ̀

Bí ọ̀làwọ́ èèyàn ti máa ń ṣe tó bá gbàlejò, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa lọ́pọ̀ yanturu.

“Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè . . . fún gbogbo àwọn ènìyàn”

25:6

  • Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, táwọn èèyàn bá jọ jẹun pa pọ̀, ńṣe nìyẹn ń fi hàn pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ara wọn

“Ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́”

  • Oúnjẹ tí a fi òróró dùn àti wáìnì sísẹ́ ṣàpẹẹrẹ àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ tí Jèhófà ń pèsè fún wa