Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  January 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 34-37

Ọlọ́run San Hesekáyà Lẹ́san Torí Pé Ó Nígbàgbọ́

Ọlọ́run San Hesekáyà Lẹ́san Torí Pé Ó Nígbàgbọ́

Senakéríbù Ọba Ásíríà rán Rábúṣákè sí Jerúsálẹ́mù, ó ní káwọn ará ìlú náà juwọ́ sílẹ̀ fún òun. Àwọn ará Ásíríà lo onírúurú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti kó àwọn Júù láyà jẹ, kí wọ́n báa lè juwọ́ sílẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n bá wọn jagun.

  • Íjíbítì pàápàá kò lè gbà yín sílẹ̀.​—Ais 36:6

  • Jèhófà kò ní jà fún yín, torí pé inú rẹ̀ kò dùn sí yín.​—Ais 36:7, 10

  • Àwọn ọmọ ogun Ásíríà lágbára gan-an, ọwọ́ kan ni wọ́n máa pa yín rẹ́.​—Ais 36:8, 9

  • Ìgbésí ayé yín á dẹrùn tẹ́ ẹ bá juwọ́ sílẹ̀ fún Ásíríà.​—Ais 36:16, 17

Hesekáyà fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà

37:1, 2, 14-20, 36

  • Ó ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ̀ ká láti múra ìlú náà sílẹ̀ de ìsàgatì

  • Ó gbàdúrà pé kí Jèhófà gba àwọn sílẹ̀, ó sì gba àwọn ará ìlú níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀

  • Ọlọ́run san Hesekáyà lẹ́san fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tó rán ańgẹ́lì kan láti pa 185,000 àwọn ọmọ ogun Ásíríà lóru ọjọ́ kan ṣoṣo