Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  January 2017

January 16-​22

Aísáyà 34-37

January 16-​22
 • Orin 31 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Ọlọ́run San Hesekáyà Lẹ́san Torí Pé Ó Nígbàgbọ́”: (10 min.)

  • Ais 36:1, 4-10, 15, 18-20​—Àwọn ará Ásíríà ṣáátá Jèhófà, wọ́n tún halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ (ip-1 386-388 ¶7-14)

  • Ais 37:1, 2, 14-20​—Hesekáyà gbọ́kàn lé Jèhófà (ip-1 389-391 ¶15-17)

  • Ais 37:33-38​—Jèhófà gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ (ip-1 391-394 ¶18-22)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Ais 35:8​—Kí ni “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́,” àwọn wo ló sì lẹ́tọ̀ọ́ láti máa rìn lójú ọ̀nà náà? (w08 5/15 26 ¶4; 27 ¶1)

  • Ais 36:2, 3, 22​—Báwo ni Ṣẹ́bínà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nípa jíjẹ́ ẹni tó ń gba ìbáwí? (w07 1/15 8 ¶6)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 36:1-12

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 24:​3, 7, 14​—Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni​—Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé o máa pa dà wá.

 • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 2Ti 3:1-5​—Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni ​—Fún un ní káàdì ìkànnì JW.ORG.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 31-32 ¶11-12​—Pe ẹni náà wá sí ìpàdé.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 91

 • Jèhófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé”: (15 min.) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo ìnasẹ̀ fídíò “Jèhófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé”.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 7 ¶1-9

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 96 àti Àdúrà