1. Ka ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí, tá a sì fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ, èyí táá jẹ́ kí onílé rí kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà.

  2. Ka ìpínrọ̀ tó wà nísàlẹ̀ ìbéèrè náà.

  3. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fi lẹ́tà wínníwínní kọ, kó o sì fi ọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí onílé rí bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí náà.

  4. O lè tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà ní kókó 2 àti 3 tí ìbéèrè náà bá ní ìpínrọ̀ míì. Tí fídíò kan bá wà lórí ìkànnì jw.org/yo tó bá ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí tí ẹ̀ ń jíròrò mu, o lè fi han ẹni náà láàárín kan nínú ìjíròrò yín.

  5. Sọ pé kí onílé dáhùn ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí kó o lè mọ̀ bóyá ó ti lóye ohun tẹ́ ẹ kọ́.