Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  January 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àǹfààní Tá A Ní Láti Kọ́ Àwọn Ibi Tí A Ti Ń Ṣe Ìjọsìn Tòótọ́ Ká sì Máa Bójú Tó Wọn

Àǹfààní Tá A Ní Láti Kọ́ Àwọn Ibi Tí A Ti Ń Ṣe Ìjọsìn Tòótọ́ Ká sì Máa Bójú Tó Wọn

Ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti ìnáwó kí wọ́n tó lè kọ́ Tẹ́ńpìlì ní Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìtara kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́lé náà. (1Kr 29:2-9; 2Kr 6:7, 8) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń bójú tó tẹ́ńpìlì náà lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ ọ tán fi hàn bóyá wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (2Ọb 22:3-6; 2Kr 28:24; 29:3) Lóde òní, àwa Kristẹni máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wa láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, a máa ń mú kí wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, a sì máa ń ṣàbójútó wọn. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lọ́nà yìí, ohun tí à ń ṣe yìí sì jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa sí i.Sm 127:1; Iṣi 7:15.

ARA OHUN TÁ A LÈ ṢE NI PÉ . . .

  • Ká máa tún àwọn ibi tá a bá lò tàbí jókòó sí nípàdé ṣe ká tó lọ sílé. Tí a kò bá ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí àwọn ìdí kan, ká rí i dájú pé àyíká ibi tá a jókòó sí wà ní mímọ́ tónítóní.

  • Ká máa kópa nínú iṣẹ́ ìmọ́tótó àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a máa ń ṣe déédéé. Àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀yà, tá a bá ń pawọ́ pọ̀ ṣe é, iṣẹ́ náà á dínkù, ayọ̀ wa á sì kún.lv ojú ìwé 92 àti 93 ìpínrọ̀ 18.

  • Ká máa fowó ṣètìlẹyìn. Kódà, inú Jèhófà dùn sí ìtìlẹ́yìn tó tọkàn wá tó dà bí ‘ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an’ tá a bá fún un.Mk 12:41-44.

  • Ká máa yọ̀ǹda ara wa tí ipò wa bá gbà bẹ́ẹ̀ láti máa kọ́ àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò, ká sì máa ṣàtúnṣe wọn. Kì í ṣe dandan ká ti nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ká tó lè yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ yìí.