Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  January 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍRÀ 1-5

Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ

Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Jèhófà ṣèlérí pé òun á mú kí àwọn èèyàn òun pa dà máa jọ́sìn òun nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pa dà dé láti ìgbèkùn Bábílónì ní. Bí àpẹẹrẹ, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe dúró. Torí náà ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà pé àwọn ò ní lè parí iṣẹ́ náà.

 1. nǹkan bí 537 Ṣ.S.K.

  Kírúsì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ tún tẹ́ńpìlì kọ́

 2. 3:3

  Oṣù keje

  Wọ́n mọ pẹpẹ; wọ́n rú ẹbọ

 3. 3:10, 11

  536 Ṣ.S.K.

  Wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀

 4. 4:23, 24

  522 Ṣ.S.K.

  Atasásítà Ọba dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró

 5. 5:1, 2

  520 Ṣ.S.K.

  Sekaráyà àti Hágáì gba àwọn èèyàn náà níyànjú láti pa dà sí ẹnu iṣẹ́ ìkọ́lé náà

 6. 6:15

  515 Ṣ.S.K.

  Wọ́n parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì