Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  January 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 33-36

Jèhófà Mọyì Ojúlówó Ìrònúpìwàdà

Jèhófà Mọyì Ojúlówó Ìrònúpìwàdà
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

MÁNÁSÈ

Jèhófà jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Ásíríà mú un, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ mú un lọ sí Bábílónì

KÍ WỌ́N TÓ MÚ UN

 • Ó ṣe pẹpẹ fún àwọn ọlọ́run èké

 • Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ

 • Ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ sílẹ̀

 • Ó mú kí ìbẹ́mìílò tan dé gbogbo orílẹ̀-èdè náà

LẸ́YÌN TÍ WỌ́N TÚ U SÍLẸ̀

 • Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi

 • Ó gbàdúrà sí Jèhófà; ó rú ẹbọ

 • Ó mú àwọn pẹpẹ tó ṣe fún àwọn ọlọ́run èké kúrò

 • Ó sọ fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé kí wọ́n máa sin Jèhófà

JÒSÁYÀ

JÁLẸ̀ ÌṢÀKÓSO RẸ̀

 • Ó wá Jèhófà

 • Ó mú ìjọsìn èké kúrò ní ilẹ̀ Júdà àti Jerúsálẹ́mù

 • Ó tún ilé Jèhófà ṣe; ó rí ìwé Òfin