Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

ILÉ ÌṢỌ́

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí máa dùn-ún gbé tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí?

Ka Bíbélì: Heb 13:18

Fi ìwé lọni: Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Torí náà, ó yẹ ká máa ṣòótọ́ ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́.

ILÉ ÌṢỌ́ (ẹ̀yìn ìwé)

Béèrè ìbéèrè: Kí lèrò rẹ nípa ìbéèrè yìí? [Ka ìbéèrè àkọ́kọ́.] Àwọn kan gbà gbọ́ pé ẹni tó bá ti kú á lọ máa gbé ní ibòmíì, àwọn kan sì gbà pé ìkú ni òpin ohun gbogbo. Kí ni ìwọ gbà gbọ́?

Ka Bíbélì: Onw 9:5

Fi ìwé lọni: Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. Màá fẹ́ kó o kà á. A máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tí mo bá pa dà wá.

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Fi ìwé lọni: Mo fẹ́ fi bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ hàn ọ́. Ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ ibi tí wàá ti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì nínú Bíbélì rẹ.

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ o ti ka Bíbélì rí? Jẹ́ kí n fi bí àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé yìí ṣe rọrùn tó hàn ọ́. [Bá a jíròrò ìbéèrè 1 nínú ẹ̀kọ́ 2.]

Ka Bíbélì: Iṣi 4:11

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.