Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn arábìnrin kan ń fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọni ní orílẹ̀-èdè Madagascar

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI January 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àti ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! lọni. Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ìjọsìn Tòótọ́ Gba Ìsapá

Fojú inú wo bí Hesekáyà Ọba ṣe múra tán láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ sọ jí pa dà. Àwọn àwòrán, máàpù àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú 2 Kíróníkà 29-30 máa jẹ́ kó o lè fojú inú wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Bí A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ohun márùn-ún tó rọrùn tó o lè ṣe láti máa fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àǹfààní Tá A Ní Láti Kọ́ Àwọn Ibi Tí A Ti Ń Ṣe Ìjọsìn Tòótọ́ Ká sì Máa Bójú Tó Wọn

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìtara àti ìfẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ní àwọn ibi ìjọsìn wa?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà Mọyì Ojúlówó Ìrònúpìwàdà

Bí Mánásè Ọba ṣe ronú pìwà dà tọkàntọkàn ní ipa rere lórí wa. Fi bí ìṣàkóso rẹ̀ ṣe rí ṣáájú kí wọ́n tó mú un lọ Bábílónì àti lẹ́yìn tí wọ́n tú u sílẹ̀ wéra. (2 Kíróníkà 33-36)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ

Àtẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Ẹ́sírà 1-5. Láì ka ọ̀pọ̀ ìṣòro tí àwọn Júù tó ń pa dà sílé láti ìgbèkùn Bábílónì ní sí, wọ́n mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò, wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì kọ́.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwọn Tó Ń Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn Ni Jèhófà Fẹ́

Ó gba pé kí Ẹ́sírà àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn-àjò pa dà sí Jerúsálẹ́mù ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ìtara fún ìjọsìn tòótọ́ àti ìgboyà. Àwòrán àti máàpù yìí máa jẹ́ kó o lè fojú inú wo bí ìrìn-àjò wọn ṣe rí.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Sọ Ohun Tó O Máa Bá Onílé Jíròrò Nígbà Tó O Bá Pa Dà Wá

Ohun mẹ́ta tó o lè ṣe tí wàá fi lè ṣe ìpadàbẹ̀wò tó múná dóko sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì.