Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

February 6-12

AÍSÁYÀ 47-51

February 6-12
 • Orin 120 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Jèhófà Máa Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣègbọràn Sí I”: (10 min.)

  • Ais 48:17—Ìjọsìn tòótọ́ dá lórí ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run (ip-2 131 ¶18)

  • Ais 48:18—Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa (ip-2 131 ¶19)

  • Ais 48:19—Ṣíṣe ìgbọràn máa jẹ́ ká rí ìbùkún tí kò lópin (ip-2 132 ¶20-21)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Ais 49:6—Báwo ni Mèsáyà ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ló ti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? (w07 1/15 9 ¶9)

  • Ais 50:1—Kí nìdí tí Jèhófà fi béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ibo wá ni ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá yín wà?” (it-1 643 ¶4-5)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 51:12-23

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Lóṣù February, àwọn ará tún lè lo ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí ìwé The Origin of Life—Five Questions Worth Asking tí wọ́n bá pàdé ọmọ iléwèé tí wọ́n ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n, àmọ́ tó ń fẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà. (Wo àpótí náà The Origin of Life—Five Questions Worth Asking.”)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 89

 • Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (7 min.) Ẹ tún lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 144-145)

 • Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Máa Ṣègbọràn sí Jèhófà: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Máa Ṣègbọràn sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà? (Owe 27:11) Àwọn ọ̀nà wo làwọn ọmọdé ti gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Jèhófà? Àwọn ọ̀nà wo làwọn àgbàlagbà ti gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Jèhófà?

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 8 ¶1-7 àti àpótí“Ìhìn Rere Lédè Tó Ju Ẹgbẹ̀ta Lé Àádọ́rin

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 98 àti Àdúrà