Ńṣe ni ìrètí dà bí ìdákọ̀ró. (Heb 6:19) Ó máa ń jẹ́ ká lè dúró gbọin tá a bá dojú kọ ìṣòro tó dà bí ijì lílè, tó fẹ́ mú kí ọkọ ìgbàgbọ́ wa sojú dé. (1Ti 1:18, 19) Lára ohun tó lè dà bí ìjì líle nígbèésí ayé wa ni ìjákulẹ̀, àdánù ohun ìní, àìsàn ọlọ́jọ́ pipẹ́, ikú ẹnì kan tá a nífẹ̀ẹ́ tàbí nǹkan míì tó lè ba ìwà títọ́ wa jẹ́.

Ìgbàgbọ́ àti ìrètí máa ń jẹ́ ká lè máa fọkàn yàwòrán àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa. (2Kọ 4:16-18; Heb 11:13, 26, 27) Torí náà, yálà ọ̀run ni ìrètí wa tàbí orí ilẹ̀ ayé, a gbọ́dọ̀ máa ronú lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì, kí ìrètí wa lè máa lágbára sí i. Tá a bá wá dojú kọ ìṣòro tó ń tánni lókun, àá ṣì máa láyọ̀.1Pe 1:6, 7.

WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ MÁA YỌ̀ NÍNÚ ÌRÈTÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tí Mósè fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere tá a lè tẹ̀ lé?

  • Kí ni ojúṣe olórí ìdílé?

  • Kí làwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè jíròrò nígbà Ìjọsìn Ìdílé?

  • Báwo ni ìrètí ṣe lè mú kó o fara da àdánwò láìmikàn?

  • Kí ni ò ń fojú sọ́nà fún?