Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  February 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fọgbọ́n Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa

Máa Fọgbọ́n Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa

Jésù kọ́ wa pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mt 10:8) À ṣì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yẹn títí dòní, ìdí nìyẹn tá a fi ń fún àwọn èèyàn ní Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa láìdáye lé e. (2Kọ 2:17) Síbẹ̀ náà, àwọn òtítọ́ pàtàkì látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde yìí. Kì í ṣe owó kékeré là ń ná láti ṣe àwọn ìtẹ̀jáde yìí, ó sì tún máa ń gba ìsapá láti kó wọn ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ jákèjádò ayé. Torí náà, ìwọnba tá a nílò ni ká máa gbà.

Ó tún yẹ ká máa lo òye nígbà tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní ìwé wa, pàápàá nígbà tá a bá ń wàásù níbi térò pọ̀ sí. (Mt 7:6) Dípò tí a ó kàn fi máa fún gbogbo àwọn tó ń kọja ní ìwé, ó dáa ká bá wọn sọ̀rọ̀ díẹ̀, ká lè mọ̀ bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Ká tó lè fún ẹnì kan ní ìwé wa, ó kéré tán, ó yẹ kó ṣe ọ̀kan lára àwọn kókó tó wà nínú àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìí. Tí kò bá dá ẹ lójú pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ó máa dáa kó o kúkú fún un ní àṣàrò kúkúrú. Àmọ́ ṣá o, tó bá ní ká fún òun ní ìwé ìròyìn tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì, kò burú tá a bá fún un ní ẹ̀dà kan.Owe 3:27, 28.