Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 52-57

Kristi Jìyà fún Wa

Kristi Jìyà fún Wa

“A tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwọn ènìyàn sì yẹra fún un . . . Àwa fúnra wa kà á sí ẹni tí ìyọnu bá, ẹni tí Ọlọ́run kọlù, tí ó sì ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́”

53:3-5

  • Àwọn èèyàn tẹ́ńbẹ́lú Jésù, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án pé ó jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì. Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ ẹ́, bí ìgbà tó fi àìsàn burúkú kọ lù ú

“Jèhófà tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí títẹ̀ ẹ́ rẹ́, . . . ohun tí Jèhófà ní inú dídùn sí yóò sì kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀”

53:10

  • Kò sí àní-àní pé ó máa dun Jèhófà wọra nígbà tó rí ìyà tí wọ́n fi jẹ Ọmọ rẹ̀, tí wọ́n sì pa á. Àmọ́ inú rẹ̀ dùn pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ láìkù síbi kan. Ikú Jésù tún fi hàn pé irọ́ gbuu ni Sátánì pa pé àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò lè jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Ó sì máa jẹ́ kí àwọn tó ronú pìwà dà rí ojúure Ọlọ́run. Ó sì tún ṣàṣeparí “ohun tí Jèhófà ní inú dídùn sí”