Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Ìròyìn nípa àwọn ọ̀dọ́ tó ń ní ìdààmú ọkàn ti wá pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ báyìí. Kí lẹrò pá a lè ṣe nípa ìṣòro yìí?

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun táwọn ọ̀dọ́ lè ṣe tí wọ́n bá ní ìdààmú ọkàn àti báwọn òbí wọn ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Kí ló ń mú kí ìdílé láyọ̀?

Ka Bíbélì: Ef 5:33

Òtítọ́: Ìgbéyàwó máa ń yọrí sí rere tí tọkọ tìyàwó bá ń fìfẹ́ bára wọn lò, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn.

TẸ́TÍ SÍ ỌLỌ́RUN KÓ O LÈ WÀ LÁÀYÈ TÍTÍ LÁÉ (ll )

Béèrè ìbéèrè: Táwọn kan bá rí onírúurú ìṣẹ̀dá àgbàyanu, ó máa ń yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì máa ń sọ bó ṣe rẹwà tó. Àmọ́ ta ló yẹ kí wọ́n fi ògo fún?

Ka Bíbélì: Iṣi 4:11

Fi ìwé lọni: Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, Ọlọ́run ló yẹ kó gba ògo àti ọlá fún àwọn nǹkan tó dá. Ohun tó wà ní ojú ìwé keje [7] ìwé yìí nìyẹn.

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ