Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  February 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 12-13

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́ Lára Nehemáyà

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́ Lára Nehemáyà

Nehemáyà fìtara gbèjà ìjọsìn tòótọ́

13:4-9, 15-21, 23-27

  • Élíáṣíbù àlùfáà àgbà jẹ́ kí Tobáyà tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ àti alátakò ní ipa burúkú lórí òun

  • Élíáṣíbù gba Tobáyà láàyè láti máa gbé nínú yàrá ìjẹun tó wà nínú tẹ́ńpìlì

  • Nehemáyà da gbogbo àga àti tábìlì Tobáyà síta, ó sọ inú gbọ̀ngàn náà di mímọ́, ó sì jẹ́ kó pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀

  • Nehemáyà túbọ̀ ń mú àwọn nǹkan tí kò mọ́ kúrò ní Jerúsálẹ́mù