Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  February 2016

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Pe Àwọn Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín Wá sí Ìrántí Ikú Kristi!

Pe Àwọn Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín Wá sí Ìrántí Ikú Kristi!
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni yìí láti February 27, a máa pe àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa bó bá ti lè ṣeé ṣe tó ká lè jọ ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ó tún yẹ ká kíyè sí àwọn tá a bá sọ̀rọ̀, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ká lè pa dà lọ bẹ̀ wọ́n wò.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

O LÈ SỌ PÉ

“À ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan. Ní March 23, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló máa kóra jọ láti rántí ikú Jésù Kristi, kí wọ́n sì gbọ́ àsọyé Bíbélì kan lọ́fẹ̀ẹ́ tó dá lórí bí ikú Jésù ṣe ṣe wá láǹfààní. Ìwé ìkésíni yìí máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ibi tá a ti máa ṣe é ládùúgbò wa àti àkókò tó máa wáyé. Ẹ jọ̀wọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ wá.”

Tí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ . . .

 • FI ÌLÉ ÌṢỌ́ LỌ̀ Ọ́

  Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.

 • JẸ́ KÓ WO FÍDÍÒ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI

  Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.

Tó o bá pa dà lọ bẹ̀ ẹ́ wò, o lè . . .

 • JẸ́ KÓ WO FÍDÍÒ KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?

  Fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lọ̀ ọ́.

 • FI ÌWÉ KÍ NI BÍBÉLÌ FI KỌ́NI GAN-AN? LỌ̀ Ọ́

  Fi àfikún àlàyé tó wà lójú ìwé 206 sí 208 ṣàlàyé púpọ̀ sí i nípa Ìrántí Ikú Kristi fún ẹni náà. Kó o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́.

 • FI ÌWÉ TẸ́TÍ SÍ ỌLỌ́RUN LỌ̀ Ọ́

  Bá onílé jíròrò ohun tí ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe tó wà lójú ìwé 18 àti 19. Kó o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́.