• Orin 106 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fún ẹnì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ ní ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi.

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fún ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ ní ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi àti ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi ojú ìwé 206 sí 208 nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ṣàlàyé ohun tí Ìrántí Ikú Kristi túmọ̀ sí fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ. Sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ bí o ṣe fẹ́ ràn án lọ́wọ́ kó lè wá sí Ìrántí Ikú Kristi.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 5

  • Pe Àwọn Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín Wá sí Ìrántí Ikú Kristi!”: (15 min.) Ìjíròrò. Sọ bí ẹ ṣe máa pín ìwé ìkésíni yìí fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín. Nígbà tó o bá ń bójú tó ìsọ̀rí tá a pè ní “Ohun Tó O Lè Ṣe,” jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ìrántí Ikú Kristi. Gba àwọn ará níyànjú láti kópa ní kíkún nígbà tá a bá ń pín ìwé ìkésíni náà, kí wọ́n pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Ṣe àṣefihàn kan.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 9 ìpínrọ̀ 14 sí 24, àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 82 (30 min.)

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 147 àti Àdúrà