Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ

Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní làwọn ọ̀dọ́ ní nínú ètò Jèhófà. Wo fídíò Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ kó o lè rí bí Cameron ṣe fi ọgbọ́n lo ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí. (Lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́.)

  • Kí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé Cameron?

  • Ìgbà wo ló ti pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣeé?

  • Báwo ló ṣe múra sílẹ̀ kó lè lọ sìn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run?

  • Àwọn nǹkan wo ni Cameron fara dà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lórílẹ̀-èdè tó lọ?

  • Kí nìdí tó fi máa ṣàǹfààní láti sin Jèhófà níbi tí a kò tíì ṣiṣẹ́ sìn rí?

  • Àwọn ìbùkún wo ni Cameron rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?

  • Kí nìdí tí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fi jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ?

  • Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì wo làwọn ọ̀dọ́ lè ní nínú ètò Jèhófà?