Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  February 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 9-11

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń Kọ́wọ́ Ti Gbogbo Ètò Tó Jẹ Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń Kọ́wọ́ Ti Gbogbo Ètò Tó Jẹ Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run

Àwọn èèyàn Ọlọ́run fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún ìsìn tòótọ́ ní onírúurú ọ̀nà

10:28-30, 32-39; 11:1, 2

  • Àwọn èèyàn náà múra sílẹ̀ fún Àjọyọ̀ Àtíbàbà bó ṣe yẹ

  • Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn náà ń kóra jọ láti tẹ́tí sí Òfin Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ kí wọ́n láyọ̀

  • Àwọn èèyàn náà jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n gbàdúrà, wọ́n sì bẹ Jèhófà pé kó bù kún àwọn

  • Àwọn èèyàn náà gbà pé àwọn á máa kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run

Onírúurú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́wọ́ ti àwọn ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ni:

  • Wọ́n ń fẹ́ kìkì àwọn tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà

  • Wọ́n ń fowó ṣètìlẹyìn

  • Wọ́n ń pa Sábáàtì mọ́

  • Wọ́n ń kó àwọn igi tí wọ́n á fi mọ pẹpẹ wá

  • Wọ́n ń fún Jèhófà ní àwọn àkọ́so wọn àti àkọ́bí àwọn nǹkan ọ̀sìn wọn