• Orin 126 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Nehemáyà Fẹ́ràn Ìjọsìn Tòótọ́”: (10 min.)

  • [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nehemáyà.]

  • Ne 1:11–2:3—Ohun tó fún Nehemáyà láyọ̀ ni bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe tẹ̀ síwájú (w06 2/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7)

  • Ne 4:14—Nehemáyà borí àwọn tó ń ta ko ìsìn tòótọ́ torí pé ó fi Jèhófà sọ́kàn (w06 2/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Ne 1:1; 2:1—Kí nìdí tá a fi lè parí èrò sí pé àkókò kan náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ka “ọdún ogún” tí Nehemáyà 1:1 àti Nehemáyà 2:1 mẹ́nu kàn? (w06 2/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 5)

  • Ne 4:17, 18—Báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè máa fi ọwọ́ kan ṣoṣo mọ ògiri? (w06 2/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: Ne 3:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Pe àfíyèsí àwọn ará sí bí akéde tá a rí nínú fídíò náà ṣe sọ ohun tó máa bá onílé jíròrò nígbà tó bá pa dà wá. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 103

 • Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ Láti Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Oṣù March Tàbí April: (15 min.) Ìjíròrò. Sọ àwọn kókó pàtàkì láti inú àpilẹ̀kọ náà, “Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Láyọ̀ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀!” (km 2/14 ojú ìwé 2) Sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká múra sílẹ̀. (Owe 21:5) Fi ọ̀rọ̀ wá àwọn akéde méjì tí wọ́n ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ rí lẹ́nu wò. Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n borí? Kí ló fún wọn láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà?

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 8 ìpínrọ̀ 1 sí 16 (30 min.)

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 135 àti Àdúrà