Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  February 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe kàyéfì nípa ìwà àgàbàgebè àtàwọn ẹ̀kọ́ èké tó wà nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn. Kí lẹ rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn lọ́jọ́ iwájú?

Ka Bíbélì: Iṣi 18:8

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn èèyàn á ṣe kúrò nínú ìsìn èké àti bí Ọlọ́run ṣe máa pa ìsìn èké run pátápátá. [Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 3 sí 6 han onílé.]

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Kí lẹ rò pé ó máa jẹ́ kí tọkọtaya lè gbé pọ̀ ní àlàáfíà?

Ka Bíbélì: Kol 3:13

Fi ìwé lọni: Àpilẹ̀kọ yìí sọ púpọ̀ sí i nípa bí àwọn tọkọtaya ṣe lè máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà. [Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 12 àti 13 han onílé.]

TẸ́TÍ SÍ ỌLỌ́RUN

Béèrè ìbéèrè: Ṣé ẹ máa fẹ́ gbé nínú ayé tó rí bí èyí? [Fi ojú ìwé 2 àti 3 han onílé, kó o sì jẹ́ kó fèsì.]

Ka Bíbélì: Jer 29:11

Fi ìwé lọni: Ìwé yìí sọ bí a ṣe lè tẹ́tí sí Ọlọ́run ká sì gbádùn àwọn ìbùkún tó ní fún wa lọ́jọ́ iwájú. [Bá onílé jíròrò ojú ìwé 4 àti 5.]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.