Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn arábìnrin kan ń fi ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run lọni ní orílẹ̀-èdè Indonesia

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI February 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Jí! àti ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run lọni. Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Nehemáyà Fẹ́ràn Ìjọsìn Tòótọ́

Fojú inú wo bí Nehemáyà ṣe sapá gan-an láti tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́ kí ìjọsìn tòótọ́ lè máa tẹ̀ síwájú. (Nehemáyà 1-4)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Alábòójútó Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Ni Nehemáyà

Nehemáyà ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti máa fi ayọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run. Fojú inú wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní oṣù Tíṣírì, ọdún 455 Ṣ.S.K. (Nehemáyà 8:1-18)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń Kọ́wọ́ Ti Gbogbo Ètò Tó Jẹ Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run

Àwọn èèyàn Ọlọ́run fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún ìsìn tòótọ́ nígbà ayé Nehemáyà. (Nehemáyà 9-11)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní làwọn ọ̀dọ́ ní nínú ètò Jèhófà táá jẹ́ kí wọ́n lè gbádùn ìgbésí ayé wọn. Àwọn ìbéèrè yìí la ó fi jíròrò fídíò náà.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́ Lára Nehemáyà

Àwòrán yìí máa jẹ́ kó o lè fojú inú wo bí Nehemáyà ṣe fìtara gbèjà ìjọsìn tòótọ́. (Nehemáyà 12-13)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Pe Àwọn Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín Wá sí Ìrántí Ikú Kristi!

Ohun tó o lè sọ tó o bá fẹ́ fún ẹnì kan ní ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2016. Àwọn ohun tó o lè ṣe láti ran ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ lọ́wọ́ wà nínú ìwé yìí.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ́sítérì Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

Fojú inú wo bí Ẹ́sítérì ṣe fìgboyà gbèjà àwọn èèyàn Jèhófà. (Ẹ́sítérì 1-5)