Sef 2:​2, 3

Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà pa wá mọ́ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀, ó kọjá pé ká kàn ya ara wa sí mímọ́ fún un, a tún gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Sefanáyà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

  • Wá Jèhófà: Ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, kó o sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ètò rẹ̀ ń fún wa

  • Wá òdodo: Máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà

  • Wá ọkàn tútù: Máa fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìfẹ́ Jèhófà kó o sì gba ìbáwí rẹ̀

Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa wá Jèhófà, òdodo àti ọkàn tútù?