Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  December 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​​—Máa Wàásù fún Gbogbo Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​​—Máa Wàásù fún Gbogbo Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè máa tẹ́wọ́ gba ìhìn rere. (Sek 8:23) Àmọ́ ta ló máa kọ́ wọn? (Ro 10:​13-15) Àǹfààní ló jẹ́, ẹrù iṣẹ́ wa sì tún ni láti wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.​—od 84 ¶10-11.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Múra sílẹ̀. Ṣé ó máa ń pàdé àwọn tó ń sọ èdè míì? O lè lo JW Language láti kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tó o lè fi bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè wọn. O tún lè lo fóònù tàbí tablet rẹ láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè mọ púpọ̀ sí i ní èdè wọn lórí jw.org

  • Wà lójúfò. Tó o bá ń wàásù láti ilé dé ilé, rí i dájú pé o wàásù fún gbogbo ẹni tó o bá rí. Wàásù fún àwọn tó ń kọjá lọ tàbí àwọn tó jókòó sínú mọ́tò, bóyá tí wọ́n ń dúró de ẹnì kan. Tó o bá ń wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí, fi sọ́kàn pé ìdí tó o fi wà níbẹ̀ ni láti wàásù fún gbogbo èèyàn

  • Ṣiṣẹ́ kára. Máa pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí o kò bá nílé. O lè pa dà lọ síbẹ̀ ní àkókò tó yàtọ̀ sí àkókò tí o kò bá wọn nílé, tàbí ọjọ́ míì tó yàtọ̀ sí ọjọ́ tí o kò bá wọn nílé. O lè kọ lẹ́tà sí àwọn onílé míì, o lè pe àwọn míì lórí tẹlifóònù, ó sì lè jẹ́ nígbà ìjẹ́rìí òpópónà lo máa pàdé àwọn míì

  • Máa ṣèbẹ̀wò. Tètè pa dà sọ́dọ̀ ẹni tó bá fìfẹ́ hàn. Tí o kò bá gbọ́ èdè onítọ̀hún, wá ẹnì kan tó gbọ́ èdè rẹ̀ kó lè ràn án lọ́wọ́. Túbọ̀ máa pa dà sọ́dọ̀ ẹni náà títí di ìgbà tí wàá fi rí akéde tó lè sọ èdè rẹ̀.​—od 94 ¶39-40

WO FÍDÍÒ WÍWÀÁSÙ NÍ “APÁ IBI JÍJÌNNÀ JÙ LỌ NÍ ILẸ̀ AYÉ,” LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin yẹn ṣe múra sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ wàásù fún àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó jìnnà gan-an? (1Kọ 9:​22, 23)

  • Àwọn nǹkan wo ló fẹ́ fa ìdíwọ́ tí wọ́n sì ní láti bójú tó?

  • Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n rí gbà?

  • Àwọn ìsapá wo lo lè ṣe láti túbọ̀ wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín?