Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  December 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Kí nìdí tó fi dà bíi pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe?

Ka Bíbélì: Jer 10:23

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé nǹkan ṣì ńbọ̀ wá dáa.

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?

Ka Bíbélì: Sm 83:18

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí àti ìdí tó fi yẹ ká máa lo orúkọ náà. [Ṣí i sí àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì​—Orúkọ Ọlọ́run.”]

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ ìgbà kan tiẹ̀ lè wà tí ikú tó jẹ́ ọ̀tá àwa èèyàn ò ní sí mọ́?

Ka Bíbélì: 1Kọ 15:26

Òtítọ́: Jèhófà máa mú ikú kúrò pátápátá.

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ