Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn ará kan ń wàásù ní ọjà kan lórílẹ̀-èdè Sierra Leone

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI December 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Jí! lọni àti láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa ikú. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ Wá Jèhófà Kí Ọjọ́ Ìbínú Rẹ̀ Tó Dé

Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà pa wá mọ́ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Sefanáyà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Di Aṣọ Ọkùnrin Tó Jẹ́ Júù Mú”

Àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè ń rọ́ wá jọ́sìn Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​​—Máa Wàásù fún Gbogbo Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ

Gbogbo èèyàn la fẹ́ wàásù ìhìnrere fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Dúró sí “Àfonífojì Àwọn Òkè Ńlá”

Kí ni “àfonífojì àwọn òkè ńlá” ń ṣàpẹẹrẹ? Báwo làwon èèyàn ṣe lè sá lọ síbẹ̀ kí wọ́n sì dúró síbẹ̀?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ohun Tuntun Táá Máa Wáyé ní Ìpàdé Àárín Ọ̀sẹ̀

Lo àlàyé ọ̀rọ̀ àti àwọn àwòrán tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun èyí tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ìkànnì, èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ṣé Ìgbéyàwó Rẹ Ń Múnú Jèhófà Dùn?

Nígbà ayé Málákì, Jèhófà Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn àwọn tó ńṣe àdàkàdekè sí ọkọ tàbí aya wọn. Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn lóde òní?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kí Ni Ìfẹ́ Tòótọ́?

Jèhófà ṣètò ìgbéyàwó lọ́nà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan á fi wà pa pọ̀ títí láé. Ó fún àwa Kristẹni ní àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n yan ẹni tí a máa fẹ́, ká sì ní ìgbéyàwó aláyọ̀.