Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ṣẹ́bínà ni ìríjú “tí ń ṣe àbójútó ilé,” Ọba Hesekáyà. Òun ni igbákejì ọba, ó sì ní ọ̀pọ̀ ojúṣe láti bójú tó.

22:15, 16

  • Ó yẹ kí Ṣẹ́bínà pèsè ohun táwọn èèyàn Jèhófà nílò

  • Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan ńláńlá ló ń wá fún ara rẹ̀

22:20-22

  • Jèhófà fi Élíákímù rọ́pò Ṣẹ́bínà

  • Ọlọ́run sọ pé òun máa fún Élíákímù ní “kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì,” èyí to fi hàn pé Ọlọ́run máa gbé agbára àti àṣẹ wọ Élíákímù

Rò ó wò ná: Báwo ni Ṣẹ́bínà ì bá ṣe lo ipò tó wà kó lè ran àwọn míì lọ́wọ́?