WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó bí Jésù, wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa wàásù ní “ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí Jésù lára, ní ti pé ó rìnrìn àjò jákèjádò Gálílì ó ń wàásù ó sì ń kọ́ni ní ìhìn rere.Ais 9:1, 2.

  • Ó ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ Jo 2:1-11 (Kánà)

  • Ó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ Mk 3:13, 14 (nítòsí Kápánáúmù)

  • Ó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè Mt 5:1–7:27 (nítòsí Kápánáúmù)

  • Ó jí ọmọ opó kan dìde Lu 7:11-17 (Náínì)

  • Ó fara han nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tó jíǹde1Kọ 15:6 (Gálílì)