Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Wọ́n ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Chile

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI December 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Jí! Lọni àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa ohun tó fa ìjìyà. Lo àbá yìí láti fi gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

‘Ẹ Jẹ́ Kí A Gòkè Lọ sí Òkè Ńlá Jèhófà’

Aísáyà ṣàpèjúwe bá a ṣe máa yí àwọn ohun ìjà ogun pa dà sí ohun èlò téèyàn lè fi ṣiṣẹ́ oko, tó fi hàn pé àlááfíà láwọn èèyàn Jèhófà á máa wá. (Aísáyà 2:4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I— Máa Lo Ìwé “Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run” Láti Dénú Ọkàn Àwọn Èèyàn

Ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” máa ń jẹ́ kí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ bí wọ́n ṣe lè fí àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò nígbèésí wọn.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Tó Ní Ìmúṣẹ

Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa wàásù ní àgbègbè Gálílì. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí Jésù lára torí pé ó wàásù ìhìn rere jákèjádò ilẹ̀ Gálílì.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Èmi Nìyí! Rán Mi!”

Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìmúratán àti ìgbàgbọ́ Aísáyà? Kẹ́kọ̀ọ́ látara ìdílé kan tí wọ́n kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ilẹ̀ Ayé Yóò Kún fún Ìmọ̀ Jèhófà

Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Párádísè orí ilẹ̀-ayé ṣe ní ìmúṣẹ nígbà àtijọ́, lọ́wọ́lọ́wọ́, àti lọ́jọ́ iwájú?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Borí Ìwà Ẹ̀tanú

Àwọn ọ̀tá méjì tẹ́lẹ̀ di arákùnrin nípa tẹ̀mí—ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń kọ́ wa.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àṣẹ Máa Ń Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹni Tó Bá Ń Ṣi Agbára Lò

Báwo ni Ṣẹ́bínà ì bá ṣe lo ipò tó wà kó lè ran àwọn mí ì lọ́wọ́? Kí nìdí tí Jèhófà ṣe fi Élíákímù rọ́pò Ṣẹ́bínà?