Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  August 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní​—⁠Ìrẹ̀lẹ̀

Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní​—⁠Ìrẹ̀lẹ̀

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:

  • Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn sún mọ́ Jèhófà.​—⁠Sm 138:6

  • Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn.​—⁠Flp 2:​3, 4

  • Ìparun ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn agbéraga.​—⁠Owe 16:18; Isk 28:⁠17

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ní kí ẹnì kan gbà ẹ́ nímọ̀ràn, kó o sì fi í sílò.​—⁠Sm 141:5; Owe 19:⁠20

  • Máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti ran àwọn míì lọ́wọ́.​—⁠Mt 20:​25-27

  • Má ṣe jẹ́ kí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tàbí ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe mú kó o máa gbéra ga.​—⁠Ro 12:3

Báwo ni mo ṣe lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn lọ́nà tó ga?

WO FÍDÍÒ NÁÀ, YẸRA FÚN OHUN TÓ LÈ BA ÌDÚRÓṢINṢIN RẸ JẸ́​ ​—⁠ÌGBÉRAGA, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Tí wọ́n bá fún wa ní ìmọ̀ràn, báwo la ṣe máa ń ṣe?

  • Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìrẹ̀lẹ̀?

  • Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?