Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  August 2017

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìgbà Wo Ni Mo Tún Lè Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà?

Ìgbà Wo Ni Mo Tún Lè Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà?

Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà á máa fi tinútinú lo ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè máa rú ẹbọ ìyìn sí Jèhófà?​—⁠Heb 13:​15, 16.

Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn oṣù kan wà nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 2018 tó ní Sátidé àti Sunday márùn-ún. Àǹfààní ni èyí sì jẹ́ fún àwọn tó jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń jáde òde ẹ̀rí nítorí iṣẹ́ wọn. Ohun míì ni pé àwọn akéde lè yàn láti lo ọgbọ̀n [30] tàbí àádọ́ta [50] wákàtí ní oṣù March àti April àti nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká.

Àmọ́ kí la lè ṣe tí a ò bá lè ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà báyìí? A lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i, ká sì gbìyànjú láti fi kún àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ipò yòówù ká wà, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà mú kí á fi ohun tó níye lórí bọlá fún un, pàápàá lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2018!​—⁠Ho 14:⁠2.

Báwo ni mo ṣe lè ní ìtara bíi ti Sabina Hernández?

WO FÍDÍÒ NÁÀ, LỌ́LÁ JÈHÓFÀ, KÒ SÓHUN TÍ MI Ò LÈ ṢE, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló mú kí Sabina pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

  • Kí lo rí kọ́ lára Sabina?

  • Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2018, oṣù wo lo máa fẹ́ ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà?