ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:

  • A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ ká lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa.​—Heb 11:6

  • Tá a bá gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́, èyí á jẹ́ ká lè fara da àdánwò.​—1Pe 1:​6, 7

  • Tá ò bá ní ìgbàgbọ́, èyí lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. ​—Heb 3:​12, 13

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tèmi àti ti ìdílé mi túbọ̀ lágbára?

WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA LÉPA OHUN TÓ LÈ MÚ KÓ O JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN​—ÌGBÀGBỌ́, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni “ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè”? (1Ti 1:5)

  • Tá a bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, àwọn nǹkan tí kò dára wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún?

  • Kí nìdí tó fi máa pọn dandan pé ká ní ìgbàgbọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá? (Heb 10:39)