Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn ará ń fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọni ní orílẹ̀-èdè Azerbaijan

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI August 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Jí! lọni àti láti kọ́ni nípa ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà San Ìlú Abọ̀rìṣà Kan Lẹ́san

Jèhófà san àwọn ará Bábílónì lẹ́san lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlá tí wọ́n fi sàga ti ìlú Tírè. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fi hàn pé òun mọrírì ìdúróṣinṣin wa àti àwọn ohun tá a yááfì?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní​—⁠Ìrẹ̀lẹ̀

Kí nìdí tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ fi ṣe pàtàkì? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Tá a bá ń gbàdúrà tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, báwo ni èyí ṣe lè mú ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Iṣẹ́ Ńlá Ni Iṣẹ́ Olùṣọ́

Àwọn olùṣọ́ ló sábà máa ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nígbà tí nǹkan aburú bá fẹ́ wọ inú ìlú. Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tí ó yan Ìsíkíẹ́lì lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti di olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní​—Ìgboyà

Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ borí ìbẹ̀rù èèyàn? Tá a bá ń ṣàṣàrò, tá à ń gbàdúrà, tá a sì gbẹ́kẹ̀lé Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe lè jẹ́ ká ní ìgboyà?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Gọ́ọ̀gù Ti Ilẹ̀ Mágọ́gù Máa Tó Pa Run

Bíbélì sọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ kí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù tó pa run àti lẹ́yìn tó bá pa run.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní​—Ìgbàgbọ́

A gbọ́dọ̀ fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ bíi ti Ábúráhámù kódà nígbà tí kò bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo la ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀ ká sì tún jẹ́ adúróṣinṣin?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bí Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí Ṣe Kàn Ọ́

Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí ń rán wa létí pé Jèhófà ní ìlànà tó ga fún ìjọsin rẹ̀ mímọ́. Báwo ni ìran yìí ṣe lè fún wa níṣìírí?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìgbà Wo Ni Mo Tún Lè Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà?

Ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe láti fi rú ẹbọ ìyìn ni pé ká ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ṣé ó wu ìwọ náà láti ṣe é kó o lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ sunwọ̀n sí i?