Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  August 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 106-109

“Ẹ Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà”

“Ẹ Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà”

Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tètè gbàgbé bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n là?

106:7, 13, 14

  • Dípò kí wọ́n pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Jèhófà, ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ àtàwọn nǹkan tara ní wọ́n gbájú mọ́

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó?

106:1-5

  • Pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe tó fi yẹ kó o máa dúpẹ́

  • Máa ṣàṣàrò lórí ìrètí ọjọ́ ọ̀la

  • Tó o bá n gbàdúrà, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn nǹkan pàtó tó ti ṣe fún ẹ