Dáfídì lo ọ̀rọ̀ àfiwé láti fi ṣàpèjúwe àánú Jèhófà.

  • 103:11

    Bó ṣe jẹ́ pé ó kọjá òye ẹ̀dá láti mọ́ bí ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ ṣe jìnnà tó sí ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ la ò ṣe lè díwọ̀n bí inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣe pọ̀ tó

  • 103:12

    Bí a ò ṣe lè mọ bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé tí Jèhófà bá ti dárí jí wà, ó máa ń mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà réré sí wa

  • 103:13

    Bí baba kan ṣe máa ń ṣaájò ọmọ rẹ̀ tó fara pa, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń fi àánú hàn sí àwọn tí wọ́n bá ronú pìwà dà, àmọ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn