“Ibi ìkọ̀kọ̀” Jèhófà la ti ń rí ààbò nípa tẹ̀mí

91:1, 2, 9-14

  • Tá a bá fẹ́ máa gbé ní ibi ìkọ̀kọ̀ Jèhófà lónìí, a gbọ́dọ̀ ṣe ìyàsímímọ́, ká sì ṣe ìrìbọmi

  • Àwọn tí kò gbẹ́kẹ̀ lè Ọlọ́run kò mọ ibi ìkọ̀kọ̀ yìí

  • Fún àwọn tó wà ní ibi ìkọ̀kọ̀ Jèhófà, kò sí ohunkóhun tàbí èèyàn èyíkéyìí tó lè mú kí wọ́n má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà tàbí nífẹ̀ẹ́ rẹ̀

“Pẹyẹpẹyẹ” náà fẹ́ dẹ pańpẹ́ mú wa

91:3

  • Àwọn ẹyẹ máa ń tètè fura gan-an, torí náà, ó máa ń ṣòro láti dẹ pańpẹ́ mú wọn

  • Àwọn pẹyẹpẹyẹ máa ń fara balẹ̀ kíyè sí ìṣesí àwọn ẹyẹ, wọ́n sì máa ń wá oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n á fi mú wọn

  • “Pẹyẹpẹyẹ náà,” Sátánì máa ń kíyè sí àwọn èèyàn Jèhófà, ó sì máa ń dẹ pańpẹ́ kó lè ba ipò tẹ̀mí wọn jẹ́

Mẹ́rin lára àwọn pańpẹ́ tó lè ṣekú pani tí Sátánì ń lò:

  • Ìbẹ̀rù Èèyàn

  • Kíkó Ọrọ̀ Jọ

  • Eré Ìnàjú Tí Kò Bójú Mu

  • Èdèkòyédè