Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Wọ́n ń fi tẹlifóònù wàásù nílùú Vienna, lórílẹ̀-èdè Austria

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI August 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Ohun tá a lè sọ tá a bá fẹ́ fi ìwé ìròyìn Jí! àti ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí Sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé lọni. Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Má Ṣe Kúrò Ní Ibi Ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ

Ibo ni “ibi ìkọ̀kọ̀” Jèhófà, báwo la sì ṣe lè rí ààbò níbẹ̀? (Sáàmù 91)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣe Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi

Kí nìdí tí àwọn àfojúsùn tẹ̀mí yìí fi ṣe pàtàkì? Báwo lo sì ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí yìí?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Bí Àwọn Àgbàlagbà Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Nìṣó

Sáàmù orí 92 fi hàn pé àwọn àgbàlagbà lè máa tàn yòò kí wọ́n sì máa so èso tẹ̀mí.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà máa ń rántí pé ekuru ni wá

Ní Sáàmù 103, Dáfídì lo ọ̀rọ̀ àfiwé láti fi ṣàpèjúwe bí àánú Jèhófà ṣe pọ̀ tó.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ẹ Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà”

Sáàmù orí 106 sọ pé ó yẹ ká mọ rírì àwọn ohun tí Jèhófà ṣe fún wa, ká má sì ṣe ya abaraámóorejẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Kí Ni Èmi Yóò San Pa Dà Fún Jèhófà?”

Báwo ni onísáàmù náà ṣe pinnu pé òun máa fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí Jèhófà? (Sáàmù 116)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa fi Òtítọ́ Kọ́ni

Fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tuntun yìí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àkànṣe Ìwàásù Láti Pín Ìwé Ìròyìn Ilé Ìṣọ́ Lóṣù September

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí dá lorí ìtùnú àti bí Ọlọ́run ṣe ń tù wá nínú.