Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 3-4

Jésù Ṣe Ìwòsàn ní Ọjọ́ Sábáàtì

Jésù Ṣe Ìwòsàn ní Ọjọ́ Sábáàtì

3:1-5

Kí nìdí tí ìwà àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù fi kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jésù gidigidi? Ìdí ni pé wọ́n gbé àwọn òfin kéékèèké kalẹ̀, èyí tó mú kí pípa òfin Sábáàtì mọ́ di ẹrù ìnira. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni kéèyàn pa kòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀. Ìgbà tí ẹ̀mí ẹnì kan bá wà nínú ewu ni wọ́n tó lè ṣe ìwòsàn fún un. Èyí fi hàn pé wọn ò ní ṣe ìwòsàn ẹni tí egungun ẹ̀ kán tàbí tó fi ibì kan rọ́ lọ́jọ́ Sábáàtì. Ó ṣe kedere pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn náà kò láàánú ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ gbẹ hangogo yẹn.