Àwọn wo la fẹ́ fi ọ̀yàyà kí káàbọ̀? Ẹnikẹ́ni tó bá wá sí àwọn ìpàdé wa, ì báà jẹ́ àwọn tó ṣẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá tàbí àwọn tá a ti jọ wà tipẹ́. (Ro 15:7; Heb 13:2) Ó lè jẹ́ àwọn ará wa tó wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tó jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni wọn ò ti wá sípàdé mọ́. Tó bá jẹ́ pé àwa la wà ní èyíkéyìí lára àwọn ipò tá a sọ yìí, ṣé a ò ní fẹ́ kí wọ́n fi ọ̀yàyà kí wa káàbọ̀? (Mt 7:12) Torí náà, á dáa tá a bá lè gbìyànjú láti máa kí àwọn tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti nígbà tí ìpàdé bá parí. Èyí á mú kí ara tu gbogbo wa, ìfẹ́ á máa gbilẹ̀ láàárín wa, a ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún Jèhófà. (Mt 5:16) Òótọ́ ni pé ó lè má ṣeé ṣe fún wa láti kí gbogbo àwọn tó wà nípàdé lọ́kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, tí kálukú wa bá ń ṣe ipa tirẹ̀, ara máa tu gbogbo wa. *

Kì í ṣe ìgbà tá a bá ń ṣe àwọn àkànṣe ìpàdé bí Ìrántí Ikú Kristi nìkan ló yẹ ká máa fọ̀yàyà kí àwọn èèyàn, ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tí àwọn ẹni tuntun bá rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa lóòótọ́, èyí á mú kí wọ́n máa yin Ọlọ́run, wọ́n sì lè wá dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn tòótọ́.Jo 13:35.

^ ìpínrọ̀ 3 Tí àwọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ àtàwọn tó mú ara wọn kúrò lẹ́gbẹ́ bá wá sípàdé, ká má gbàgbé ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká fi ààlà sí àjọṣe wa pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.1Kọ 5:11; 2Jo 10.