Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  April 2017

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 25-28

Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà

Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà

Jeremáyà kìlọ̀ pé Jerúsálẹ́mù máa dahoro bí ìlú Ṣílò

26:6

  • Ìgbà kan wà tí wọ́n tọ́jú àpótí ẹ̀rí tó ṣàpẹẹrẹ pé Jèhófà wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ sí ìlú Ṣílò

  • Jèhófà gbà kí àwọn Filísínì gbé Àpótí náà, bó ṣe di pé kò pa dà sí Ṣílò mọ́ nìyẹn

Àwọn àlùfáà, wòlíì àtàwọn èèyan náà lérí pé àwọn máa pa Jeremáyà

26:8, 9, 12, 13

  • Àwọn èèyàn náà gbá Jeremáyà mú torí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ máa pa run

  • Jeremáyà kò pa iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́ tì, kó wá sá lọ

Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà

26:16, 24

  • Jeremáyà jẹ́ onígboyà, Jèhófà kò sì fi í sílẹ̀

  • Jèhófà lo ọkùnrin onígboyà náà, Áhíkámù láti dáàbò bo Jeremáyà

Torí pé Jèhófà ti Jeremáyà lẹ́yìn tó sì fún un níṣìírí, ogójì [40] ọdún gbáko ló fi wàásù ohun táwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí