Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Lóde òní, àwọn èèyàn máa ń ṣe fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n nípa agbára abàmì, bí àwọn oṣó, àwọn àjẹ́ àtàwọn iwin. Ṣẹ́ ẹ rò pé irú àwọn fíìmù bí èyí léwu fún wa àbí eré lásán náà ni?

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ ìdí tí ọ̀rọ̀ nípa agbára abàmì fi gba àwọn èèyàn lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ àti ẹni tó ń dárí àwọn ohun abàmì náà.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa yanjú ìṣòro aráyé?

Ka Bíbélì: Mt 6:10

Òtítọ́: Tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso láyé, àlàáfíà, ìṣọ̀kan àti ààbò máa wà lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lọ́run.

KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN? (Ìpadàbẹ̀wò)

Béèrè ìbéèrè: [Sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà.] Báwo ni ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso?

Ka Bíbélì: Sm 37:29; Ais 65:21-23

Fi ìwé lọni: [Fi ìwé pẹlẹbẹ Ìròyìn Ayọ̀ han onílé.] Ẹ̀kọ́ 7 nínú ìwé yìí sọ àǹfààní témi àtẹ̀yin máa rí nígbà tí Ọlọ́run bá mú àwọn ìlérí yìí ṣẹ. [Fi ìwé pẹlẹbẹ náà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.