Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  April 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 16-20

Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Rere Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ń Fúnni Lókun

Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Rere Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ń Fúnni Lókun

Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbani nímọ̀ràn máa gbéni ró

16:4, 5

  • Ìrònú dorí Jóòbù kodò, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn, torí náà ó nílò ìtùnú àti ìṣírí

  • Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò tù ú nínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń dá a lẹ́bi tí wọ́n sì dá kún ìṣòro rẹ̀

Ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí Bílídádì sọ sí Jóòbù mú kí Jóòbù fi ìbínú sọ̀rọ̀

19:2, 25

  • Jóòbù bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí òun kú kí ara lè tu òun

  • Jóòbù pọkàn pọ̀ sórí ìrètí àjíǹde, ó sì fara dàá délẹ̀délẹ̀