Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ohun Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò

Ohun Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò

Láti January 2016 ni àpilẹ̀kọ kan ti ń jáde ní ẹ̀yìn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí à ń fi sóde. A pe àkọlé rẹ̀ ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ.” A ṣe ohun tuntun yìí ká lè máa fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. A ṣe é bíi ti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa. Ó ní ìbéèrè tó máa jẹ́ ká mọ èrò ẹni tá a fẹ́ wàásù fún, ìdáhùn tó bá Bíbélì mu àti àwọn kókó míì tá a lè jọ jíròrò.

A lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú onílé tó bá gbádùn bí a ṣe bá a fọ̀rọ̀wérọ̀. Máa fi ohun tuntun yìí bọ́ àwọn tí ebi tẹ̀mí ń pa yó.—Mt 5:6.

BÍ O ṢE LÈ LÒ Ó:

  1. Béèrè ìbéèrè, ní kí onílé sọ èrò rẹ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè náà

  2. Tẹ́tí sí ìdáhùn rẹ̀, kó o sì gbóríyìn fún un

  3. Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lábẹ́ àkòrí tá a pé ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ,” kó o sì ní kí onílé sọ èrò rẹ̀ nípa ẹsẹ náà. Tó bá ṣì fẹ́ kí ẹ máa bá ọ̀rọ̀ yín lọ, bá a jíròrò kókó kan lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Kí Làwọn Nǹkan Míì Tí Bíbélì Sọ?”

  4. Fi ìwé ìròyìn náà lọ̀ ọ́

  5. Ṣètò láti pa dà lọ bẹ̀ ẹ́ wò kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìbéèrè kejì