Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

April 4 sí 10

JÓÒBÙ 16-20

April 4 sí 10
 • Orin 79 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Rere Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ń Fúnni Lókun”: (10 min.)

  • Job 16:4, 5—Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbani nímọ̀ràn máa gbéni ró (w90 3/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 àti 2)

  • Job 19:2—Ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí Bílídádì sọ sí Jóòbù mú kí Jóòbù fi ìbínú sọ̀rọ̀ (w06 3/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 6; w94 10/1 ojú ìwé 32)

  • Job 19:25—Nígbà tí wàhálà bá Jóòbù dé góńgó, ìrètí àjíǹde tù ú nínú (w06 3/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 5; it-2 735 ojú ìwé 735 ìpínrọ̀ 2 àti 3)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Job 19:20—Kí ni Jóòbù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ‘bí awọ eyín mi ni mo fi yèbọ́’? (w06 3/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1; it-2 ojú ìwé 977 ìpínrọ̀ 1)

  • Job 19:26—Báwo ni Jóòbù ṣe “rí Ọlọ́run,” nígbà tí èèyàn kankan ò lè rí Jèhófà? (w94 11/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 17)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: Job 19:1-23 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI