Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  April 2016

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 33-37

Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ Máa Ń Sọ Ọ̀rọ̀ Tó Gbéni Ró

Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ Máa Ń Sọ Ọ̀rọ̀ Tó Gbéni Ró
WÒÓ
Ọ̀rọ̀
Àwòrán

Nígbà tí Élíhù dá sí ọ̀rọ̀ tí Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń sọ, ọ̀rọ̀ tó sọ yàtọ̀ pátápátá sí ti Élífásì, Bílídádì àti Sófárì. Ohun tó sọ àti ọwọ́ tó fi mú Jóòbù yàtọ̀ sí tiwọn. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti agbaninímọ̀ràn tó dáńgájíá. Àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ fún wa.

ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÓ YẸ KÍ AGBANINÍMỌ̀RÀN TÓ DÁŃGÁJÍÁ NÍ

ÉLÍHÙ FI ÀPẸẸRẸ RERE LÉLẸ̀

32:4-7, 11, 12; 33:1

 

 • SÙÚRÙ

 • ẸNI TÓ Ń TẸ́TÍ SÍLẸ̀

 • ẸNI TÓ Ń BỌ̀WỌ̀ FÚNNI

 
 • Élíhù ní sùúrù kí àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀ tán kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀

 • Bí Élíhù ṣe tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa jẹ́ kó lóye ọ̀rọ̀ tó wà ńlẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀

 • Ó dárúkọ Jóòbù bó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, ó sì bá Jóòbù sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́

 

33:6, 7, 32

 

 • ÌRẸ̀LẸ̀

 • ẸNI TÓ ṢEÉ SÚN MỌ́

 • ÌYỌ́NÚ

 
 • Élíhù ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti inúure, ó sọ pé aláìpé ni òun náà

 • Ó fi ọ̀rọ̀ Jóòbù ro ara rẹ̀ wò

 

33:24, 25; 35:2, 5

 

 • ÌWỌ̀NTÚNWỌ̀NSÌ

 • INÚURERE

 • ÌBẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN

 
 • Élíhù rọra tọ́ Jóòbù sọ́nà, ó jẹ́ kó mọ̀ pé èrò tí kò tọ́ ló ní

 • Élíhù ran Jóòbù lọ́wọ́ láti mọ̀ pé òdodo tirẹ̀ kọ́ ló ṣe pàtàkì jù

 • Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Élíhù bá Jóòbù sọ mú kó ṣeé ṣe fún Jóòbù láti gba ìtọ́sọ́nà púpọ̀ sí i lọ́dọ̀ Jèhófà