Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  April 2016

 MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

A Máa Pín Ìwé Ìkésíni sí Àpéjọ Àgbègbè

A Máa Pín Ìwé Ìkésíni sí Àpéjọ Àgbègbè

Lọ́dọọdún, a máa ń hára gàgà láti gbádùn àsè tẹ̀mí ní àwọn àpéjọ àgbègbè wa. A máa pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ yìí bó bá ti lè ṣeé ṣe tó kí àwọn náà lè tọ́ oore Jèhófà wò. (Sm 34:8) Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ọ̀nà tó dára jù láti pín ìwé ìkésíni yìí.

ÀWỌN OHUN TÓ YẸ KÍ N FI SỌ́KÀN

  • Ìgbà wo ni àpéjọ àgbègbè wa bọ́ sí?

  • Ìgbà wo ni ìjọ wa máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni?

  • Ìgbà wo ni ìjọ wa á máa ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá?

  • Kí làwọn àfojúsùn mi nígbà ìpolongo yìí?

  • Àwọn wo ni mo fẹ́ pè?

KÍ LO MÁA SỌ?

Lẹ́yìn tó o bá ti kí onílé dáadáa, o lè sọ pé:

“À ń pín ìwé ìkésíni yìí kárí ayé láti pe àwọn èèyàn sí àpéjọ pàtàkì kan. Ọjọ́ tá a máa ṣe é, aago tá a máa bẹ̀rẹ̀ àti ibi tá a ti máa ṣe é wà nínú ìwé ìkésíni yìí. A ó máa retí yín.”

PA DÀ LỌ BẸ̀ WỌ́N WÒ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a fẹ́ pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ àgbègbè bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ó yẹ ká ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa.

Fi ìwé ìròyìn àti ìwé ìkésíni lọni pa pọ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀.