Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 28-32

Jóòbù Fi Àpẹẹrẹ Ìwà Títọ́ Lélẹ̀

Jóòbù Fi Àpẹẹrẹ Ìwà Títọ́ Lélẹ̀

Jóòbù pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà

31:1

  • Ó darí ojú rẹ̀ bó ṣe yẹ, ìyàwó rẹ̀ nìkan sì ni ọkàn rẹ̀ máa ń fà sí

Jóòbù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú bó ṣe bá àwọn èèyàn lò

31:13-15

  • Ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í ṣe ojúsàájú, ó sì láàánú. Ó máa ń gba tàwọn èèyàn rò láìka ipò wọn sí àti bóyá wọ́n rí ṣe tàbí wọn ò rí ṣe

Jóòbù lawọ́, kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan

31:16-19

  • Ó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì máa ń ṣoore fáwọn aláìní